Yoruba Translation – Citizens Data Agency Exhibition

Káàbọ̀ sí Àjọ Détà àwọn Ọmọ Ìlú!

À ńrí àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ tó wà láàrin gbogbo apá ayé wa, láàrin àwọn ìlú, àwọn ilé àti àpò wa. Àwọn ìfarakínra wọ̀nyí ńṣẹ̀dá iye détà ńlá èyítí àwọn àjọ àti ìjọba kójọ. Ó seéṣe kí àwọn àǹfààní  wà láti gba àlékún iye détà, sùgbọ́n ó tún múkí ìpele àwọn ewu ìpamọ́ sí ẹnikọ̀ọ̀kan gbèrú síi bíi títa tàbí ìlòkulò détà, jíjí détà àti àlékún ìsọ̀fíntótó àti ìmójútó. A gbèrò wípé ó nílò kí á ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ dáradára síi láti lóye àwọn ìlò détà, àwọn ewu pínpín détà wọn àti pípèsè ìmọ̀ràn àti ohun èlò lórí bí wọ́n yóò ṣe dáàbòbo ara wọn. Àjọ Détà àwọn Ọmọ Orílẹ̀-èdè jẹ́ olùpèsè iṣẹ́ àròsọ̀ tó ń pèsè awọn iṣẹ́ ìgbèrò láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ pẹ̀lí détà wọn àti dáàbòbo ìkọ̀kọ̀ wọn lórí ayélujára.

Àwọn ìtàkurọ̀sọ tó yí ìpamọ́ détà ká kìí sábà kan àwọn ènìyàn láti àwọn ẹgbẹ́ tí a kò náání. Bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n ń dojúkọ àwọn ìpèníjà àti ewu ìpamọ́ détà, ìnílò àti ìrírí wọn kò sí nínú ètò ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn. A ti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ agbègbè méjì tí àwọn ènìyàn ńdarí tí wọ́n sì ńràn àwọn ènìyàn tó wá láti agbègbè ẹ̀yà kékeré lọ́wọ́, Datakirk àti Amina, pẹ̀lú ìfojúsùn wíwá ìrànlọ́wọ́ détà ìsinsìnyí àti ọjọ́ iwájú kiri nípasẹ̀ ìkópa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní síṣẹ̀-n-tẹ̀lé àti àjọṣe àkójọpọ̀ iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ détà tí a gbèrò láyìká àwọn ìrírí wọn àti àwọn ohun tí wọ́n nílò.

Ìfihàn ní gbangba yìí ń s’àfihàn àwọn iṣẹ́ ìgbèrò máàrún nípasẹ̀ àwọn ẹ̀tọ̀ ìfarakínra, bẹ̀rẹ̀ láti àkíyèsí détà, àwọn ẹ̀tọ́ détà, síṣe àkóso détà àwọn mìíràn, ìjábọ̀ àpapọ̀ détà àti ìdámọ́ràn détà. Bíótilẹ̀jẹpé a kò le pèsè ìrànlọ́wọ́ détà gangan lónìí, a lérò wípé ìsàfihàn ní gbangba ń wú ọ lórí láti gbèrò lórí àwọn ìnílò ìpamọ́ détà araré àti irú àwọn iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ détà tí a le nílò ní ọjọ́ iwájú.

Mọ Détà Rẹ

Iṣẹ́ ‘Mọ détà rẹ!’ jẹ́ ètò ìmúdàgbà ẹlẹ́gbẹ́-n-jẹgbẹ́ tí ńran ènìyàn lọ́wọ́ láti kọ́ bí wọn yóò ti máa sàkóso détà wọn àti bí wọn ṣe le pààlà détà àrìsì ara-ẹni. Ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú elétò orílẹ̀-èdè kan, iṣẹ́ náà yóò pèsè àwọn àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ oní ìfarakínra níbití àwọn ènìyàn ti le kọ́ nípa àwọn ẹ̀tọ́ détà wọn, àwọn ìṣẹ àti ohun-èlò mímú ohun ìkọ̀kọ̀ gbèrú, pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun àti tìwòyí. A ti ṣe àwọn ìpín ní àjọṣepọ̀ laàrin àjọ náà àti àwọn ilé-iṣẹ́ àwùjọ ti agbègbè, ní rírí dájú wípé wọ́n lálòpẹ́ wọ́n sí ṣé lò, bá àwọn ìní àwùjọ mu wọ́n sì wà ní àwọn èdè tó yẹ.

Àwọn afaratọrẹ fún iṣẹ́ ìsìn tó ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àkíyèsí détà ni yọ́ọ̀ ma darí ìpín náà èyítí ó ńpésé wọn sílẹ̀ láti kọ́ àwọn yọ̀ọ́kù nípa àkòrí náà. Ohun àfojúsùn mímú ẹ̀tọ̀ náà dàgbà nípasẹ̀ àwọn afaratọrẹ fún iṣẹ́ ìsìn ni láti múkí àwùjọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìmọ̀ dàgbà kí wọ́n sì ní ìgboyà pẹ̀lú ìpamọ́ détà wọn, tí a sì ró wọn lágbára láti kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ àti ìrírí wọn.

Àjọ náà yóò ṣe ìgbédìde ẹ̀tọ̀ orí asọ̀rọ̀mágbèsì ‘Mọ Détà Rẹ!’ kan èyítí ó ńgba àwọn olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tóní ìmọ́ ìpamọ́ détà l’álejò, tí ó ńpèsè ìwífún tó wúlò lórí bí o ṣe le mú ìpamọ́ détà rẹ gbòòrò, àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ńpín àwọn ìrírí ara-ẹni wọn, àti jíjábọ̀ lórí àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun àti àwọn ewu détà. Ètò asọ̀rọ̀mágbèsì náà ńpèsè ìpín ‘pè wọlé’ níbití àwọn ènìyàn ti le pè wọlé pẹ̀lú àwọn ìbéèrè tàbí ìfòyà nípa détà, ààbò détà tábí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìpamọ́ wọn. Yẹ àwọ̀rán máàpù détà tí a sẹ̀dá wò èyítí ó ńs’àfihàn ọ̀pọ̀ orísìírísìí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn fí ńsẹ̀dá àti pín détà, àti irú àjọ àti ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ńpín détà wọn pẹ̀lú. Wo àwọn ìbéèrè tí a pèsè kí o sì ṣe àfikún àwọn ìgbèrò àkọsílẹ̀ tìrẹ sórí àwọ̀rán máàpù náà.

Ìrànlọ́wọ́ àwọn Ẹ̀tọ́ Détà

Àwọn ènìyàn ò mọ àwọn ẹ̀tọ́ tó yí détà wọn ká nígbàgbogbo, tàbí àwọn ohun-èlò àti ìrànlọ́wọ́ tó wà láàrọ́wọ́tó sí wọn bí wọ́n bá ti ní ìrírí ìpalára orí ayélujára kan tàbí ní ìsòro kan pẹ̀lú détà wọn. Síṣe iṣẹ́ ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn gbọ̀ngàn òfin agbègbè àti àwọn elétò orílẹ̀-èdè, àjọ náà yóò pèsè iṣẹ́ ìmọ̀ràn ẹ̀ẹ̀kan láti jẹ̀kí àwọn ènìyàn lóye ohun ti ẹ̀tọ détà wọn jẹ́ nígbàtí wọ́n bá ní ìrírí ìpalára orí ayélujára tàbí ti ní láti pín détà orí ẹ̀rọ lọ́nà àìbófinmu.

Iṣẹ́ náà le darí àwọn ènìyàn sí àwọn ilé-iṣẹ́ tó wà èyítí ó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tàbí òfin, pẹ̀lú àjọ náà tó ń pèsè ìmọ̀ yíyẹ lórí bí ó ti dára jùlọ láti lò wọ́n. Àwọn olùdámọ̀ràn le fún àwọn ènìyàn ní ohun èlò, dábàá àwọn iṣẹ́ míìràn tí àjọ náà ńpèsè, bíi Ìdámọ̀ràn Détà, tí ó sì ńpèsè ètò ìgbaniwí fún àwọn ènìyàn tó nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí asojú òfin, pàápàá jùlọ tí wọ́n bá nílò láti kópa pẹ̀lú àwọn àjọ àti Ìmọ̀ ẹ̀rọ Ńlá. 

Nípasẹ̀ àwọn ìpàdépọ̀ wọ̀nyí, àjọ náà yóò tọpinpin àwọn irú ìpalára orí ayélujára tí a jábọ̀ láti lóye dáradára ààlà ìsinsìnyí àti ẹ̀rí ohun tí àwọn ìpalára orí ayélujára tó yẹ kí ìjọba gbọdọ̀ máa ràn lọ́wọ́ síi. 

Wá sọ̀rọ̀ sí olùrànlọ́wọ́ Ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀tọ́ Détà tí o le pín ìwífún lórí ohun tí ẹ̀tọ́ détà jẹ́, pín àwọn ohun èlò kọ̀ọ̀kan lórí bí a ṣe le dáàbòbò détà rẹ kí o sì fi ọ́ hàn sí àwọn iṣẹ́ yòókù nínú àjọ náà. (Jọ̀wọ́ s’àkíyèsí èyí kìí ṣe ojúlówó iṣẹ́, a kàn le pín ìwífún a kò sì le pèsè ìmọ̀ràn òfin tàbí àwọn ìbéèrè ìdáhùn.)

Àwọn tí o Yẹ láti Gba Détà

Pẹ̀lu bí ìmọ̀-ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣé ń wá láàrọ́wọ́tọ́ síi, àwọn ènìyàn ń gbé ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀rọ wá sí ilé àti àdúgbò wọn. Bíótilẹ̀jẹpé àwọn ẹ̀rọ náà le ṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ìmójútó, agbára ìmúsẹ́ṣe àti ààbò, àwọn ẹ̀rọ le máa gba détà lóòrèkóòrè, bóyá ìyẹn jẹ́ détà ibùdó, ìkásílẹ̀ fánrán tàbí ohùn, tàbí ìtọpinpin ìlò tàbí ìhùwàsí. Ẹ̀yí túmọ̀sí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ńgba détà nípa ara wọn àti àwọn yòókù, sùgbọ́n àwọn ènìyàn le má mọ̀ nípa ewu àti ipa tó seéṣe kí èyí fà lórí àwọn yòókù. A tún le pín détà yìí pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ti ńṣe ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹ̀rọ náà. Pẹ̀lú àwọn apá ìgbe-ayé àwọn ènìyàn tí a mójútó dáradára ó túmọ̀sí wípé àwọn àròjinlẹ̀ ara-ẹni sínú ayé wa ní àwọn ile-iṣẹ̀ aládàáni ti gbàjọ tí wọn sì pín tàbí tà fún àwọn alàgàta.

Láti ṣe ìwúrí àwọn ìbánisọ̀rọ̀ l’áyìká ìfọwọ́sí àti gbígba détà tó yẹ, àjọ náà yóò sdá ìpolongo kan láti sún àwọn ènìyàn síwájú àti ṣe kóríyá fún wọn láti jẹ́ ‘Àwọn tí o Yẹ láti Gba Détà’. Nípasẹ̀ àwọn ìpolówó ìwé àwòrán ńlá àti ẹlẹ́rọ, àfojúsùn ni láti s’afihan pàtàkì ìtọ́jú fún àti ìbọ̀wọ́fún détà ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ewu tó seéṣe tàbí ipa nígbàtí a bá ń gba détà ara-ẹni nípa àwọn ẹlọ̀míràn. Ìpolongo náà fojúsí àwọon àkòrí bíi ààbò ara-ẹni, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, ìtọpinpin àwọn mọ́lẹ́bí tàbí olólùfẹ́ l’orí ẹ̀rọ, pínpín ìwífún (pẹ̀lú èrèdí tàbí nípa àsìṣe) nípa awọn yòókù lórí ìkànnì ìbánidọ́ọ̀rẹ́ àti síṣe àsàyàn ìmọ̀ nípa àwọn ilé-iṣẹ́ láti pín détà rẹ pẹ̀lú wọn. Àjọ náà yóò pèsè ìtọ́sọ́nà kan lórí bí o ṣe le jẹ́ tí o ẹnití o yẹ láti gba détà àti gẹ́gẹ́bí ara àwọn ìpín ìpolongo ní àwọn àwùjọ tó wà bíi ile-ìyáwèékà níbití àwọn ènìyàn ti le kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe le mójútó détà ara wọn àti ti ẹlọ̀míràn.

Wo àwọn ìwé àtẹ̀jáde ńlá méjì wa kí o sì ronú lórí bí ò ṣé ńgba détà nípa àwọn ènìyàn yòókù bí àwọn ọ̀nà bá sì wà tí o fi le mójútó détà ara rẹ àti ti ẹlọ̀míràn.

Ìjábọ̀ Àkójọ Détà

Lọ́wọ́lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ojúṣe láyìká ìpamọ́ détà dálé ẹnikọ̀ọ̀kan, tó nílò láti tẹ àwọn ìlànà ìpamọ́ àti àwọn ìbéèrè láyìká kúkìsì àti àkójọ détà. Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ àti ápùù tí àwọn ajọ àti ilé-iṣẹ́ ńlá s’àkóso, ó le sòro láti lóye ohun tí ò ń faramọ́ àtí wípé nígbà mìíràn kòsì dàbí pé o le yàn bí o ṣe le gba àti lo détà rẹ. Ní ìdáhùn sí èyí àjọ náà yóò ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú elétò orílẹ̀-èdè kan láti s’ètò ìlànà ìjábọ̀ àkójọ kan láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gba ẹ̀rí láàyíká àwọn ọ̀rọ̀ ìpamọ́ détà.

Iṣẹ́ yìí ńfojúsùn láti lo agbára àkójọ láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti kópa àti tako àwọn ilé-iṣẹ́ tàbí àjọ tí kò wà pẹ̀lú détà àwọn ènìyàn. Síṣe iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́/ìọrẹ-àánú àwùjọ agbègbè, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ àti àwùjọ agbègbè yóò dá àwọn ọ̀rọ̀ détà pàtó mọ̀ tàbí àwọn ilé-iṣẹ́ àti iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwùjọ láti gba détà láti bá wọn yanjú ọ̀rọ̀ tó so mọ́ isẹ̀lẹ̀ náà. Àjọ náà yóò siṣẹ́ nípò àwùjọ agbègbè láti pinnu lórí ẹ̀nà kan tó múnádóko láti kojú iṣẹ̀lẹ̀ détà, bóyá nípa bíbá ilé-iṣẹ́ sọ̀rọ̀ tààrà, wíwá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ agbègbè, ìfihàn nípasẹ̀ ìròyìn àti àwọn akọ̀wé ìròhìn, tàbí bíbẹ àwọn olùṣẹ̀dá ìlànà iṣe.

A ní ìtàgé ayélujára níbití o tí le ṣe àfikún àwọn àbá rẹ fún èyítí àwọn ọ̀rọ̀ ìpamọ́ détà tí o lérò wípé àwọn àjọ gbọdọ̀ wádìí (fún àpẹrẹ, àwọn sọ́ọ̀bù orí ayélujára ń pín détà rẹ láì gbàṣẹ). Lábẹ́ orísìírísìí irú ìṣẹ̀lẹ̀ ìpamọ́ détà, o le ṣe àkọsílẹ̀ ìwé tàbí pín ìrírí rẹ pẹ̀lú ìsẹ̀lẹ̀ pàtó kan tàbí ilé-iṣẹ́ láti dásí àgbájọ ẹ̀rí.

Ìgbaninímọ̀ràn Détà

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti ní ìrírí ewu orí ayélujára tí àwọn ìrírí wọ̀nyí le kóbá ìmọ̀lára àti ìlera ọpọlọ àwọn ènìyàn. Àwọn iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ détà f’ojúsí apá ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti òfin ti pípèsè àwọn ojútùú àìpẹ́ sí ìsòro kan. Ẹ̀wẹ̀, a kò tíì bá àìní àti pèsè ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀lára fún àwọn ènìyàn tí détà jíjò tàbí àwọn ìpalára orí ayélujára ti kóbà.

Nínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìlera, àjọ náà yóò pèse pàtó àwọn àkókò ìgbaninímọ̀ràn détà fún àwọn ènìyàn tóní ìrírí àwọn ìpalára orí ayélujára tàbí s’àníyàn nípa ìpamọ́ détà wọn. Àwọn akọṣẹ́mọṣẹ́ ìgbaninímọ̀ràn tí ń pèse àwọn àkókò ojúkojú fún ẹnikọ̀ọ̀kan, àwọn ìdílé tàbí àwọn aláàbásiṣẹ́pọ̀ ni yóò darí iṣẹ́ yìí; wọn yóò máa pèsè ààyè láti pín àwọn ìsẹ̀lẹ̀ àti gba ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀lára láti múkí ìlera ọpọlọ wọn gbèrú èyítí ìrúfin détà tàbí àwọn ìpalára orí ayélujára ti kóbá.

A ti kọ́ àwọn agbaninímọ̀ràn  láti l’óye àti ran ẹnikọ̀ọ̀kan, àwọn aláàbásiṣẹ́pọ̀ àti àwọn ìdílé lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìmọ̀lára tó wáyé láti àwọn ìpalára orí ayélujára àti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìpamọ́ détà àti ipa tí ó le ní lórí ìlera ọpọlọ àti ara, àwọn ìbáṣepọ̀ tàbí ìsoro ìsúná. Kìíṣe títọ́jú ààmì ààrùn (ìfòyà tó seéṣe, wàhálà, ìrẹ̀wẹ̀sì, PTSD abbl) nìkan, sùgbọ́n síṣe iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olúkúlùkù tí a kọ́ tó lóye pàtó ìrírí ewú ńlá orí ayélujára (bíi jìbìtì orí ayélujára, olè ìdánimọ̀, ìdúnkokò orí ayélujára, pínpín àwọn àwòrán láì gbàṣẹ abbl).

Àjọ náà yóò tún ṣe ìgbésókè àwọn ẹgbẹ́ ìrànlọ́wọ́ akẹgbẹ́ ẹni láàyíká pàtó ewu ayélujára yóò pèsè ààyè kan fún ènìyàn láti sópọ̀ mọ́ olúkúlùkù kí o sì pín àwọn ìrírí kanna láti mọ wípé wọn kò dáwà. 

Lo àsìkò yìí látí jọ́kòó ní ààyè ìgbaninímọ̀ràn détà kí o sì wo àwọn káàdì ìbéèrè tí a pèsè. A lẹ́rò wípé wọ́n pèsè àkókò ìrònú nípa ipá tí ìmọ̀ ẹ̀rọ orí ayélujára àti détà le ní lórí àwọn ìmọ̀lára àti ìlera ọpọlọ wa. Bí ó bàá fẹ́, o le ṣe àfikún àwọn ìdáhùn rẹ sí ara ògiri kí o sì pín àwọn ìrírí rẹ pẹ̀lú àwọn yòókù tàbí kí o mú káàdì rẹ pẹ̀lú rẹ.

Ètò Ìwádìí

Ìwádìí iṣẹ́ yìí fojúsùn láti wá ìnílò détà àwọn ènìyàn lónìí àti lọ́jọ́ iwájú, pẹ̀lú ìfojúsùn ìlóye bí a ti le mú ìpamọ́ àti ààbò fú àwọn ènìyàn dára síi nípa lílo àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ orí ayélujára. Ipa gíga wà lórí àwọn ẹgbẹ́ tí a kò nọ́ọ́ní ní àwùjọ wa, èyítí ó nílò kí a yanjú àti gbà nígbàtí à bá ń múkí ìrànlọ́wọ́ ìpamọ́ détà gbèrú síi. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn àwùjọ nílò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọ̀nà láti pẹ̀lú àti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohùn, ìmọ̀ àti ìrírí lọ́wọ́.

Wíwá láti wádìí bí ìrànlọ́wọ́ ìpamọ́ détà ti le rí fún àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀ àwọn àwùjọ tí a kò nọ́ọ́ní, a ṣe ìbásiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àwùjọ aláàbásiṣẹ́pọ̀ méjì – Amina and Datakirk –  tó pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn láti àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀yà kékeré. Datakirk jẹ́ iṣẹ́ àwùjọ tó wà ní Edinburgh èyítí ó ńgbèrò láti ró àwọn ènìyàn lágbára kúrò ní ẹgbẹ́ àìlágbára nínú ọrọ̀-ajé détà nípa pípèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fun àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀kọ́ détà àti ìmọ̀ ìtú sí wẹ́wẹ́. Amina jẹ́ ilé ìtọrẹ àánú jákèjádò Scotland èyítí ó ń ṣe ìrónilágbára àti ìrànlọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin Mùsùlùmí àti BME nípa jíjẹ́ ìsopẹ̀ pàtàkì láàrin wọn àti àwọn ìdènà tí wọ́n ńdojúkọ lójojúmọ́. Àwọn aláàbásiṣẹ́pọ̀ méjèèjì ran iṣẹ́ náà lọ́wọ́ nípa gbígba àwọn olùkópa, tí wọ́n jọ́ ńsàkóso àwọn ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè àwọn iṣẹ́ àti àbájáde.

Pẹ̀lú aláàbásiṣẹ́pọ̀ kọ̀ọ̀kan a ṣe ìkópa àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìwádìí mẹrin kí o sì lo ìkópa àti àwọn ọ̀nà àgbékalẹ̀ ìgbẹ̀rò láti wádìí ipò líle yìí lọ́nà àfojú-inú-wò àti ti ìbániṣe. Ní ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ a fojúsun lórí  kíkọ́ àkíyèsí détà, bíbi àwọn olùkópa léèrè láti sẹ̀dá àwọn àwóran mápùù ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n mú jáde àti pín, sáájú ríronú jinlẹ̀ lórí àwọn ewu tó seẹ́ṣe kó wà láàyíká pínpín détà lórí ayélujára. Ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ kejì fojúsun síṣe àwọn ìsẹ̀lẹ̀ àfojú-inú-wò mẹrin, ní ìfojúsun láti pe àwọn olùkópa níjà láti ronú jinlẹ̀ lórí orísìírísìí àwọn ọ̀nà tí a fi le dáàbòbò tàbí s’àkóso détà náà kí o sì jíròrò àwọn ìnílò ìrànlọ́wọ́ détà ọjọ́ iwájú tó seéṣe. Àwọn ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ kẹta àti ikẹrin dálé àjọṣe àwọn iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ détà ọjọ́ iwájú àfojú-inú-wò àti iṣẹ́ àròsọ̀ ti ‘Àjọ Détà àwọn Ọmọ Orílẹ̀-èdè’ fúnrarẹ̀.

Ìfihàn ní gbangba yìí jẹ́ àyọrísí iṣẹ́ náà, tó ń s’àfihàn àwọn ìrò inú àti àgbékalẹ̀ olùkópa nípa irú ìrànlọ́wọ́ détà tó yẹ kò wà ní ọjọ́ iwájú. A lérò pé ìfihàn ní gbangba ti wú ọ lórí láti ronú jinlẹ̀ lórí ìnílò ìpamọ́ détà ararẹ àti àwọn irú iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ détà tí a le nílò ní ọjọ́ iwájú.